×

Ní orúkọ Ọlọ́hun, Ọba Àjọkẹ́ ayé, Ọba Àṣàkẹ́ ọ̀run

Islaamu ni ẹsin Oluwa gbogbo agbaye

Tani Oluwa rẹ?

Eyi ni ibeere tí ó tobi julọ ni aye; o sì jẹ ibeere pataki ti eniyan gbọdọ mọ idahun rẹ̀.

Oluwa wa, Oun ni Ẹniti O ṣẹda sanma ati ilẹ, O sì nsọ omi ojo kalẹ lati sanma, O sì n fi mú awọn eso ati awọn igi jade kó lè jẹ́ ounjẹ fun wa ati fun awọn ẹranko ti a n jẹ,Oun naa ni O ṣẹda wa, O ṣẹda awọn baba wa, O ṣẹda gbogbo nkan, Oun sì ni O dá oru ati ọsan, àti pé Oun ni O ṣe oru ni asiko oorun ati ìsinmi, O sì ṣe ọ̀sán ní asiko wiwa ounjẹ ati àsìkò fún wíwá ìjẹ-ìmuOun ni O tẹ òòrùn, òṣùpá, awọn irawọ, ati awọn odo lori ba fun wa, O si rọ awọn ẹranko fun wa tí a fi n jẹ ninu wọ́n, a sì n ṣe anfaani lara awọn wàrà wọn ati irun ara wọn.

Kini awọn iroyin Oluwa gbogbo agbaye?

Oluwa ni O dá gbogbo ẹda, Oun ni O n ṣe amọna wọn lọ sibi ododo ati imọna, Oun ni O nṣe akoso gbogbo ọrọ ẹda, Oun ni O npese ijẹ-imu fun wọn, Oun ni Ẹnití O ni gbogbo ohun tí o wa ni aye ati ohun ti o wa ni ọrun, gbogbo nkan Òun ni Olukapa rẹ̀, gbogbo ohun ti o yato si I tiRẹ̀ nii ṣe,Oun ni Alaaye ti kii ku, ti kii sun, Oun ni Oludaduro ti o ṣe pé pẹlu aṣẹ Rẹ̀ ni gbogbo ẹda alaaye ṣe duro, Oun ni Ẹniti aanu Rẹ̀ yi gbogbo nnkan ká, ati pe Oun ni Ẹniti ko si ohun kankan tó pamọ fun Un ni ilẹ ati sanma.Kò sí ohun tí ó da bíi Rẹ̀, ati pé Oun ni Olugbọ, Oluri, O wà loke awọn sanma ní Ẹniti O rọrọ̀ tayọ awọn ẹda Rẹ̀, awọn ẹda ni wọ́n n bukata si I, kò ki n bọ́ sí inu ẹda Rẹ, nkankan ninu awọn ẹda Rẹ̀ ko leè bọ́ sí inu Rẹ̀, Mimọ ni fun Un, Ọba tí Ó ga,Oluwa ni O dá agbaye ti a nwò yii pẹlu gbogbo awọn ètò rẹ̀ ti wọn wa déédéé tí wọn kii kùnà, yala o jẹ awọn eto ara eniyan ati ẹranko ni tabi awọn eto aye ti o wa ni ayika wa, pẹ̀lú oorun rẹ, ati awọn irawọ rẹ, ati awọn nǹkan míì tó para pọ̀ di àgbáyé.

Ati pé gbogbo nkan tí a n jọsin fun lẹyin Rẹ kò lè ṣe anfaani tabi inira kankan fun ara rẹ̀, nitori naa bawo ni yoo ṣe ni ikapa lati ṣe anfaani fun ẹniti n jọsin fun un, tabi lati ká inira kuro fun ẹni naa.

Kíni ẹ̀tọ́ Oluwa wa lori wa?

Dajudaju ẹ̀tọ́ Rẹ̀ lori gbogbo eniyan ni pé kí wọ́n jọsin fun Un ní Oun nìkan ṣoṣo, kí wọ́n sì má ṣe ẹbọ kankan pẹlu Rẹ̀, wọn kò gbọdọ jọsin fun eniyan miran lẹyin Rẹ̀ tabi papọ mọ Ọn, abi okuta, odo, nkan bọrọgidi, irawọ, tabi ohunkóhun, bi ko ṣe pe kí wọn ṣe ijọsin wọn ní mimọ fun Ọlọhun Oluwa gbogbo agbaye.

Kíni ẹ̀tọ́ awọn eniyan ní ọdọ Oluwa wọn?

Dajudaju ẹ̀tọ́ àwọn ènìyàn ní ọdọ Ọlọ́hun tí wọ́n bá jọ́sìn fun Un, ni kí Ó ta wọ́n lọrẹ iṣẹmi daada ni aye, iṣẹmi tí wọ́n máa rí ààbò, ifayabalẹ, àlàáfíà, ìfọ̀kànbalẹ̀, àti ìtẹ́lọ́rùn ninu rẹ, tí ó bá sì di ile ikẹyin, ki Ó fi wọ́n sínú Alujannah, níbi tí ìgbádùn ayerare wà ati iṣẹmi gbere, tí wọ́n bá sì ṣẹ̀ Ẹ, tí wọ́n yapa aṣẹ Rẹ̀, Ó máa ṣe iṣẹmi wọn ní iṣẹmi buruku ati ibanujẹ, kódà ki wọ́n maa lérò pé awọn wà ninu idunnu ati ifayabalẹ, ati pé tí ó bá di ọjọ ikẹyin, O maa fi wọ́n sinu ina ti wọn kò nii jade kuro ninu rẹ, ìyà ayeraye si n bẹ fun wọn ninu rẹ, ati iṣẹmi gbere.

Kí ni ìdí bíbẹláyé wa? Ati pe nítorí kí ni wọ́n fi ṣẹda wa?

Dajudaju Ọlọhun Ọba Ọlọrẹ sọ fun wa pé Oun dá wa nitori idi pataki kan, òun naa ni ki a maa jọsin fun Oun nikan ṣoṣo, ki a sì má ṣe ẹbọ kankan pẹlu Rẹ̀, O sì là bọwa lọrun pé ki a maa gbe ori ilẹ pẹlu daadaa ati atunṣe, ẹnikẹni tí ó bá jọsin fun nkan miiran yatọ si Ọlọhun ti O ṣẹda rẹ, onítọ̀hún kò mọ̀ idi ti a fi da a, bẹẹ ni kò ṣe ojuṣe rẹ si Ẹlẹ́dàá rẹ, ati pe ẹnikẹni ti o ba ṣe ibajẹ lori ilẹ, onítọ̀hún kò mọ̀ iṣẹ ti a yàn fun un.

Báwo ni a ṣe fẹ́ jọ́sìn fun Olúwa wa?

Dajudaju Ọlọhun – titobi fun Un – kò da wa ki O wá fi wa silẹ lásán, bẹẹ ni kò ṣe igbesi aye wa ni erepa lasan, bi ko ṣe pe O ṣẹ̀ṣà awọn ojiṣẹ laarin awọn eniyan ti O rán wọn sí awọn ijọ wọn, awọn ni wọ́n pé julọ ni ìwà laarin awọn eniyan, tí wọ́n sì mọ́ julọ ní ọkàn ati ẹmi, nítorí náà O sọ awọn iwe iranṣẹ kalẹ fun wọn, O sì kó gbogbo ohun tí ó jẹ dandan ki eniyan mọ nipa Ọlọhun sinu rẹ, ati nipa gbigbe awọn eniyan dide ni ọjọ Ajinde, òun naa ni ọjọ iṣiro iṣẹ ati ẹsan,Awọn ojiṣẹ naa jiṣẹ fun awọn ijọ wọn bí wọ́n ṣe máa jọsin fun Oluwa wọn, wọ́n sì ṣalaye fun wọn bí a ṣe n jọsin ati awọn asiko rẹ ati ẹsan rẹ ni aye ati ọrun, wọ́n sì kilọ fun wọn kuro nibi ohun ti Oluwa wọn ṣe leewọ fun wọn ninu awọn ounjẹ, ati nǹkan mimu, ati ibalopọ tọkọtaya, wọ́n tọ́ wọn si ọna àwọn ìwà rere, wọ́n sì kọ̀ fun wọn kuro nibi àwọn ìwà buruku.

Ẹ̀sìn wo ni Ọlọ́hun - titobi fun Un - máa tẹ́wọ́ gbà?

Ẹsin ti Ọlọhun máa tẹwọ gba ni ẹsin Islam, àti pé oun ni ẹsin ti gbogbo awọn Anabi mú wá, Ọlọhun kò nii tẹwọ gba ẹsin kankan ni ọjọ igbende yatọ si i, gbogbo ẹsin tí awọn eniyan n ṣe yàtọ̀ sí Islam ẹsin irọ ni, kò nii ṣe olujọsin naa ni anfaani, bi ko ṣe pe aburu ni yoo fà fun un ni aye ati ọrun.

Kini awọn ipilẹ ati awọn origun ẹsin (Islam) yii?

Ọlọhun ṣe ẹsin yii ní irọrun fun awọn ẹru Rẹ̀, eyi tó tobi julọ ninu awọn origun rẹ ni ki o gba Ọlọhun gbọ pé Oun ni Oluwa ati Ọlọhun, ki o sì gba awọn Malaika Rẹ gbọ, ati awọn tira Rẹ, ati awọn ojiṣẹ Rẹ, ati ọjọ ikẹyin, ati kadara, oo waa jẹrii pé ko si ọlọhun kan tó lẹtọọ si ijọsin ayafi Allah, àti pé dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni, ki o máa gberun duro, ki o máa yọ saka tí ó bá ti wọ owo rẹ, ki o maa gba awẹ Ramadan tí ó jẹ́ oṣu kan ninu ọdun, ki o sì lọ si Ilé láéláé tí Anabi Ibraheem - Alafia kó maa ba a - kọ́ si Makkah pẹlu aṣẹ Oluwa Rẹ lati lọ ṣe iṣẹ Hajj fun Ọlọhun, tí o bá ní ikapa lati lọ,ki o jìnà sí ohun ti Ọlọhun ṣe leewọ fun ọ, gẹgẹ bi ẹbọ, pipa eniyan, àgbèrè, ati jijẹ owo eewọ, tí o bá ti gba Ọlọhun gbọ, ti o ṣe awọn iṣẹ ijọsin wọnyii, ti o sì jina si awọn nkan eewọ wọnyii, Musulumi ni ọ ni aye, ti o bá sì di ọjọ Ajinde, Ọlọhun yoo ta ọ lọrẹ idẹra ayeraye ati iṣẹmi gbere ninu Alujannah.

Ṣé Islam jẹ́ ẹsin fun ijọ kan tabi ẹ̀yà kan?

Islam ni ẹsin Ọlọhun fun gbogbo eniyan, ko si ọlá ninu rẹ fun ẹnikan lori ẹlomiran ayafi pẹlu ibẹru Ọlọhun ati iṣẹ rere, dọgbadọgba ni awọn eniyan wà ninu rẹ.

Bawo ni awọn eniyan ṣe máa mọ̀ pé olododo ni awọn ojiṣẹ, ki ikẹ ati ọlà Ọlọhun maa ba wọn?

Awọn eniyan maa mọ pe olododo ni awọn ojiṣẹ nipasẹ awọn ọna ti o pọ̀, ninu rẹ ni:

Ohun ti wọ́n mu wa ninu ododo ati imọna bá laakaye mu ati adamọ tó ni àlàáfíà, awọn làákàyè si jẹrii si pe o dara, ẹniti kìí ṣe ojiṣẹ Ọlọhun kò lè mu iru rẹ wa.

Ohun tí awọn ojiṣẹ mú wá, dídára ẹsin awọn ènìyàn àti ayé wọn wà ninu rẹ, ati idurodeede awọn alamọri wọn, ati gbígbé ọ̀làjú wọn ró, àti ṣiṣọ ẹ̀sìn wọn, ọpọlọ wọn, dukia wọn ati ọmọluabi wọn.

Awọn ojiṣẹ Ọlọhun - ki àlàáfíà maa ba wọn - kii beere owó lọwọ awọn eniyan lori didari wọn sí ibi oore ati imọna, bi ko ṣe pe wọ́n maa n reti ẹsan wọn lati ọdọ Oluwa wọn ni.

Ohun ti awọn ojiṣẹ mú wá ododo ati amọdaju ni, kò sí iyemeji nibẹ, kò tako ara wọn, kò sì darudapọ, ati pé gbogbo anabi kọ̀ọ̀kan ni o n pe awọn anabi tó saaju rẹ lododo, ó si n pepe lọ sibi iru ohun ti wọn pepe si.

Ọlọhun n ṣe atilẹyin fun awọn ojiṣẹ - àlàáfíà ki o maa ba wọn - pẹlu awọn àmì ti o foju hàn ati awọn iṣẹ iyanu ti n borí, tí Ọlọhun nṣe ni ọwọ wọn lati lè jẹ ẹri ododo pé ojiṣẹ ni wọ́n lati ọdọ Ọlọhun, eyi tí ó tobi julọ ninu awọn iṣẹ iyanu awọn Anabi ni iṣẹ iyanu ojiṣẹ ikẹhin Anabi Muhammad - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - oun naa ni Kuraani Alapọn-ọnle.

kini Kuraani Alapọn-ọnle?

Kuraani Alapọn-ọnle ni tira Oluwa gbogbo agbaye, òun ni ọrọ Ọlọhun ti Malaika Jibril - ki alaafia Ọlọhun maa ba a - mú sọkalẹ wá bá Anabi Muhammad, ó wà ninu rẹ̀ gbogbo ohun ti Ọlọhun ṣe ni ọranyan fun awọn eniyan lati mọ nipa Allah, awọn Malaika Rẹ, awọn tira Rẹ, awọn ojiṣẹ Rẹ, ọjọ́ ikẹyin, ati kadara, rere rẹ ati aburu rẹ,Ó tun wà ninu rẹ alaye awọn ijọsin tó jẹ́ ọranyan, ati àwọn eyi tó jẹ́ eewọ tí a gbọ́dọ̀ wa iṣọra kuro nibẹ, ati awọn ìwà rere ati iwa buruku, àti gbogbo ohun tí ó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn awọn ènìyàn, ayé wọn, àti ọrun wọn, ìwé ìyanu kan ni tí Ọlọhun fi pe àwọn ènìyàn nija pé kí wọ́n mú iru rẹ wa, iwe naa sì jẹ́ ohun ti a daabo bo titi di Ọjọ Ajinde pẹlu ede ti wọn fi sọ ọ kalẹ, arafi kankan kò dinku ninu rẹ, wọn kò sì yí gbolohun kankan pada ninu rẹ.

Kí ni ẹ̀rí àjíǹde àti ìṣírò iṣẹ?

Ṣé o kò rí ilẹ tí ó wà ní òkù tí kò sí iṣẹmi ninu rẹ̀, nígbà tí omi ojo bá rọ̀ sórí rẹ̀, ó máa gbọ̀n, ó sì máa wu gbogbo irugbin tó dara jáde, dajudaju Ẹnití Ó jí ilẹ pada O ni agbara lati sọ àwọn òkú di alààyè,Dajudaju Ẹniti O dá eniyan lati ara àtọ̀ omi yẹpẹrẹ, O ni agbara lati gbe e dide ni Ọjọ Ajinde, ki O sì ṣe iṣiro iṣẹ rẹ fun un, ati ki O san an ni ẹsan tó pé julọ, ti o bá jẹ pe rere lo ṣe yoo gbẹsan rere, ti o ba sì jẹ pe aburu lo ṣe yoo gbẹsan aburu,Dajudaju Ẹni tí O dá awọn sanma, ilẹ, àti awọn ìràwọ̀, O ní agbara lati tún ènìyàn da; nítorí pé titun eniyan da ni ẹlẹẹkeji rọrun ju dida awọn sanma ati ilẹ lọ.

Kíni yoo ṣẹlẹ ní Ọjọ Ajinde?

Ọlọhun – titobi fun Un – yoo gbe gbogbo ẹda dide soke lati inu awọn saare wọn, lẹyin naa yoo ṣe iṣiro fun wọn lori awọn iṣẹ wọn, ẹniti o ba ní igbagbọ, ti o sì pe awọn ojiṣẹ lododo, O maa mu u wọ inu Alujannah, eyi ti o jẹ idẹra ayeraye tí kò rú wúyẹ́ rí ninu ọkan eniyan latara titobi rẹ, ẹniti o ba sì ṣe aigbagbọ, O maa mu u wọ inu Ina, eyi ti o jẹ ìyà ayeraye ti eniyan kò lè ronu rẹ, ti eniyan ba ti wọ inu Alujannah tabi Ina, kò nii ku mọ laelae, yoo si maa bẹ gbere ninu idẹra tabi ìyà.

Ti eniyan ba fẹ wọ inu ẹsin Islam, kini yoo ṣe, ati pé ṣé awọn ààtò ìsìn kan wà tí ó gbọdọ ṣe abi awọn eniyan kan wà tí wọ́n gbọdọ yọnda fun un?

Ti eniyan ba ti mọ pe Islam ni ẹsin ododo, ati pe oun ni ẹsin Oluwa gbogbo agbaye, o gbọdọ yara lati lọ wọ inu ẹsin Islam ni; nítorí pé tí ododo bá ti foju han si onilaakaye eniyan, ó gbọ́dọ̀ sare sí i ni, kò tún gbọdọ fi falẹ̀ mọ,Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ wọ inu ẹ̀sìn Islam kò di dandan fun un pé ki o ṣe àwọn ààtò ìsìn kan pàtó, bẹ́ẹ̀ ni kò di dandan fun un pé kó wà lọ́dọ̀ ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n tí ìyẹn bá waye níwájú musulumi kan tàbí ní ibùdó ẹ̀kọ́ nípa Isilaamu kan, oore lori oore ni o jẹ, bi bẹẹ kọ, o ti tó fun un lati wọnu Isilaamu pẹlu kó sọ pe: (Ash'hadu an laa ilaha illa Allah, wa ash'hadu anna Muhammadan rasuulullah), ni ẹniti o mọ itumọ rẹ, tí ó sì gba a gbọ lododo, pẹ̀lú ìyẹn ni ó ṣe maa di musulumi; lẹyin naa yoo maa kọ awọn ofin Islam yókù diẹdiẹ, nitori kí o le maa ṣe awọn ohun tí Ọlọ́hun ṣe ní ọranyan le e lori.

--

معلومات المادة باللغة العربية